segunda-feira, 15 de fevereiro de 2016

Yorùbá


Our Yoruba Lesson and Books We Use | DNVlogsLife | VEDA 2015 Day 1

                                                                  

Orúkọọ́ mi ni Wálé. Mo jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní Yunifásítì ti Texas ní Austin. Mo fẹ́ràn ilé-ìwéè mi gan-an ni nítorí pé gbogbo ohun tí ó lè mú kí ẹ̀kọ́ rọ ènìyàn lọ̀rùn ni ó wà níbẹ̀ àgàgà nínú kíláàsìì mi. 
Oríṣiríṣi nnkan ni ó wà nínú kíláàsìì mi. Láraa wọn ni àga‚ tábìlì, àwòrán‚ kọ̀npútà‚ mọ́nítọ̀‚máòsì‚ kííbọọdù‚ ìwé atúmọ̀-èdè‚ pẹ́ẹ̀nì‚ pẹ́nsùlù‚ rúlà‚ ìrésà‚ fídíò‚ síídiì‚ fáìlì‚ máàpù àgbáyé‚ ṣọ́ọ̀kì‚ pátákó-ìkọ̀wé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ
Lẹ́yìn èyí‚ a tún lè rí àwọn nnkan mìíràn tí wọ́n mú kíláàsìì mi yàtọ̀ sí kíláàsì mìíràn ni Yunifásítì bíi ìlẹ̀kùn aláràbarà‚ fèrèsé aláràbarà‚ iná ìlẹ́tíríìkì‚ àjà‚ apẹ̀rẹ̀-ìdalẹ̀nùsí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ
Mo fẹ́ràn ilé-ìwéè mi lọ́pọ̀lọpọ̀. Mo sì máa n fi í yangàn láàárín àwọn ọ̀rẹ́ẹ̀ mi nítorí pé náánní náànnì náánní‚ ohun a ní là á náánní bí ọmọ aṣẹ́gità ṣe n náánní èpo igi.


Nenhum comentário:

Postar um comentário