quarta-feira, 25 de novembro de 2015

Música sacra

Orin mímọ́ (música sacra)

                                                      



E JE KA DIPO JESU KRISTI MU
KA MOKAN KURO NINU ANIYAN
AYE TI YIO FO LO
KA LE RI GBALA
GBEKE RE LE, GBEKE LE FE RE
GBEKE RE LE, GBOJU RE SOKE
GBEKE RE LE, DAN ANU RE WO
SA GBEKE RE LE JESU
AMIN

                                                           
  


Iwà Rere 

Eyin funfun lẹsọ erin 
Ọmọ rere lẹsọ obi 
Ade ori lẹsọ kabiyesi 
Iwa rere lẹsọ eda 

Oruka ọwọ lẹsọ igbeyawo 
Dikaka dikuku lẹsọ alakọwe 
Bibeli Mimọ lẹsọ oni igbagbọ 
Iwa rere lẹsọ eda 

Ọbẹ to dun lẹsọ iṣasun 
Ṣe ti ka lulu ka kọrin ayọ lẹsọ tiwa 
Ade ori lẹsọ kabiyesi 
Bibeli Mimọ lẹsọ oni igbagbọ 
Alafia pipe ni baba ẹsọ 
Iwa rere lẹsọ ẹda 

Iwà Rere, Will never go out of style, Ẹ jẹ a se dada ọmọ araye, Ka fi ife lo, Ka fi iyọnu lo, Ẹni gbadura ko wu wà rere, Iwà Rere, Iwà Rere, Iwà Rere, Iwà ni ẹsin. 





Oni Dodo, Oni Moin-Moin
Oni dodo, oni moin-moin
Nigba ti won o ta won gbe gba ka le
Ewa wo ija ni Lafiaji




Oro Oluwa, ko ni lo lai se
Ife Oluwa, ko ni lo lai se
Imo Oluwa, ko ni lo lai se 


Oun mo ri e, ko ba mi leru
Oun mo ri e, ko gbin mi lokan
O ti e ye ko fo mi laya
Sugbon mo ti pinu, la ti di mu
Olorun o dodo ni
Si be mo pinu lati mu okan ro
Tori mo mo pe 

Oro Oluwa, ko ni lo lai se
Ife Oluwa, ko ni lo lai se
Imo Oluwa, ko ni lo lai se
Ko ni lo lai se
Ko ni lo lai se o
Igbagbo e , lo gbe ileri awon ase mu 

Ibanije le wa, sibe oro e ase
Ikoro le ko , sugbon adun la ja si
Mo gboju mi sa pa oke
Iranwo mi be lati Olorun ododo
Idaniloju mu ireti wa tori mo mo pe 


Oro re si mi, ko ni lo lai se
Ife re si mi rere ni, ko ni lo lai se
Imo Oluwa o, ko ni lo lai se 

Olorun ki se eniyan to ma n se’ke
O ti wi be, a se be
Dandan lo n je
Bo ti le wu ko ri, oro re ase
Olepe di e, sugbon pe ko ye…hmmm, rarara
Ofifo a dopo
Irora a di ironu, ka ni ireti
Adun, a po, a pe
Adirigi, aferegere, a pe 

Igbagbo re ko ma mi se, ileri a se
Igbagbo re ko ma mi se, ileri a ma se
Igbagbo re ko ma mi se, ileri a se 

Oun o ri le ma ba o leru
Oun o ri le ma mi e lokan
O ti e le ma fo o laya
Sugbon ko ti pinu la ti di mu
Olorun o dodo ni
Si be pinu lati mu okan ro
Tori a jo mo ni pe 

Oro re si wa, ko ni lo lai se
Ife Oluwa si wa rere ni, ko ni lo lai se
Imo Oluwa o, ko ni lo lai se 

Oko jo pe o buru ni, ko ni buru fun o omo eniyan
Oro re ki ye, ko ni lo lai se
Mojukuro ninu juju to yoka loju re, iranwo wa….mo ju re soke,
Ko ni lo lai se
******
Gba lolu, gba loluto, gba loluto ati oludari, oro e rere ni
ko ni lo lai se
eh Oro Oluwa o, ko ni lo lai se
Ni gba ti mo gbeke le olu emi, mi o ni ri ituju kan lailailai
ko ni lo lai se
Mo gba lo luranlowo mi, oun lo ran mi lowo, oro re ko ni lo lai se
ko ni lo lai se
Oti wi be, a se be fun mi
Mo n duro, mo n duro
ko ni lo lai se
Eh eh Oro Oluwa, ko ni lo, ko ni lo, ko ni lo lai se
Gba be, gba be, gba be
ko ni lo lai se
Oro re si wa rere ni
ko ni lo lai se
Tu ju re ka, tu ju re ka , oro re ko ni lo lai se
ko ni lo lai se
Bi o ti le wu ko ri,
ko ni lo lai se gba be
hmmm oro Oluwa

Bíblia


Àwọn Ìwé Bíbélì.
Livros da Bíblia.