sábado, 14 de junho de 2014

Ẹ́kísódù ( Êxodo) 20:1-26

Ẹ́kísódù ( Êxodo) 20:1-26 
Ìtúmọ̀: Olùkọ́ Orlandes 




Texto bíblico para aprender yorubá e somente yorubá, o idioma dos orixás e do candomblé. 



20 Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, pé:
20 E Deus passou a falar todas estas palavras, dizendo:
Ọlọ́run = Deus supremo.
Sì ( conj. pré-v.) = e, além disso, também. Liga sentenças, porém, não liga substantivos; nesse caso, usar " àti". É posicionado depois do sujeito e antes do verbo.
bẹ̀rẹ̀ sí = começou a
sọ = falar
gbogbo = todo, toda, todos, todas
ọ̀rọ̀= palavra
wọ̀nyí, = estas, estes, esses, essas.
pé = que, para que, a fim de que.

2  Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ, tí ó mú ọ jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, kúrò ní ilé ẹrú.  
2  Eu sou Jeová, teu Deus, que te fiz sair da terra do Egito, da casa dos escravos.
Èmi = eu
Ni = ser, é
Jèhófà = Jeová,  Yahweh ou Javé (Yahvéh)
Ọlọ́run = Deus
rẹ, ẹ = seu, sua, de você
tí = que
ó = ele, ela
mú = tomar, capturar, agarrar.
ọ = você
jáde = sair, ir para fora.
kúrò = afastar-se, mover-se para, distanciar-se.
ilẹ̀ = terra, solo, chão.
Íjíbítì = Egito
ní = no, na, em. 
ilé = casa
ẹrú = escravo

3  Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ní àwọn ọlọ́run èyíkéyìí mìíràn níṣojú mi.
3  Não deves ter quaisquer outros deuses em oposição à minha pessoa.
Ìwọ = você
kò = não
gbọ́dọ̀ = dever, arriscar, precisar, ousar
ní = ter, possuir. Dizer.
àwọn, wọn  = eles elas.
àwọn ọlọ́run =  deuses
èyíkéyìí = qualquer, quaisquer
mìíràn = outro
níṣojú = na frente ( em oposição)
mi = mim
4  Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe ère gbígbẹ́ fún ara rẹ tàbí ìrísí tí ó dà bí ohunkóhun tí ó wà nínú ọ̀run lókè tàbí tí ó wà lábẹ́ ilẹ̀ tàbí tí ó wà nínú omi lábẹ́ ilẹ̀.
4 Não deves fazer para ti imagem esculpida, nem semelhança de algo que há nos céus em cima, ou do que há na terra embaixo, ou do que há nas águas abaixo da terra.
Ìwọ = você
kò = não
gbọ́dọ̀ = dever, arriscar, precisar, ousar.
ṣe = fazer
ère = imagem
gbígbẹ́ = cortado, escavado. Esculpido
fún = para
ara = corpo
rẹ = seu
tàbí = ou
ìrísí = forma
tí = que
ó = ele, ela
dà = moldar em metal, fundir. Tender a fazer algo. Tornar-se, vir a ser. Trair, delatar, ao contrário. Digerir. Fazer uma oferenda. Dirigir, donduzir, cuidar. Derramar, despejar água, colocar para fora, esvaziar.
bí  = como
ohunkóhun = qualquer coisa
wà = estar, ser, existir, haver. Implica a existência ou a presença de algo.
wà = cavar. Abraçar, prender, apertar. Monopolizar.
lábẹ́ = sob, embaixo de
ilẹ̀ = terra, solo, chão
nínú = dentro, no interior de
omi = água

5  Ìwọ kò gbọ́dọ̀ tẹrí ba fún wọn tàbí kí a sún ọ láti sìn wọ́n, nítorí èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ jẹ́ Ọlọ́run tí ń béèrè ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe, tí ń mú ìyà ìṣìnà àwọn baba wá sórí àwọn ọmọ, sórí ìran kẹta àti sórí ìran kẹrin, ní ti àwọn tí ó kórìíra mi.
5  Não te deves curvar diante delas, nem ser induzido a servi-las, porque eu, Jeová, teu Deus, sou um Deus que exige devoção exclusiva,* trazendo punição pelo erro dos pais sobre os filhos, sobre a terceira geração e sobre a quarta geração* no caso dos que me odeiam.
6  ṣùgbọ́n tí ó ń ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí ìran ẹgbẹ̀rún ní ti àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ mi, tí wọ́n sì ń pa àwọn àṣẹ mi mọ́.
6  mas usando de benevolência para com a milésima geração no caso dos que me amam e que guardam os meus mandamentos.
7 Ìwọ kò gbọ́dọ̀ lo orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ lọ́nà tí kò ní láárí, nítorí Jèhófà kò ní ṣàìfi ìyà jẹ ẹni tí ó lo orúkọ rẹ̀ lọ́nà tí kò ní láárí.
7 Não deves tomar o nome de Jeová, teu Deus, dum modo fútil, pois Jeová não deixará impune aquele que tomar seu nome dum modo fútil.
8  Máa rántí ọjọ́ sábáàtì láti kà á sí ọlọ́wọ̀.
8  Lembrando o dia de sábado para o manteres sagrado.
9  kí ìwọ ṣe iṣẹ́ ìsìn, kí o sì ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ ní ọjọ́ mẹ́fà.  
9  deves prestar serviço e tens de fazer toda a tua obra por seis dias.
10  Ṣùgbọ́n ọjọ́ keje jẹ́ sábáàtì fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí, ìwọ tàbí ọmọkùnrin rẹ tàbí ọmọbìnrin rẹ, ẹrúkùnrin rẹ tàbí ẹrúbìnrin rẹ tàbí ẹran agbéléjẹ̀ rẹ tàbí àtìpó rẹ tí ó wà nínú àwọn ẹnubodè rẹ.
10  Mas o sétimo dia é um sábado para Jeová, teu Deus. Não deves fazer nenhuma obra, nem tu, nem teu filho, nem tua filha, nem teu escravo, nem tua escrava, nem teu animal doméstico, nem teu residente forasteiro que está dentro dos teus portões.
11  Nítorí ọjọ́ mẹ́fà ni Jèhófà ṣe ọ̀run àti ilẹ̀ ayé, òkun àti ohun gbogbo tí ó wà nínú wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sinmi ní ọjọ́ keje. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi bù kún ọjọ́ sábáàtì, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe é ní ọlọ́wọ̀.
11  Pois em seis dias fez Jeová os céus e a terra, o mar e tudo o que neles há, e no sétimo dia passou a descansar. É por isso que Jeová abençoou o dia de sábado e passou a fazê-lo sagrado.
12  Bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ  kí àwọn ọjọ́ rẹ bàa lè gùn lórí ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ.
12  Honra a teu pai e a tua mãe, a fim de que os teus dias se prolonguem sobre o solo que Jeová, teu Deus, te dá.
13  Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣìkà pànìyàn.
13  Não deves assassinar.
14  Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe panṣágà.
14  Não deves cometer adultério.
15  Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jalè.
15  Não deves furtar.
16  Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ́rìí lọ́nà èké gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí lòdì sí ọmọnìkejì rẹ.
16  Não deves testificar uma falsidade contra o teu próximo.
17  “Ojú rẹ kò gbọ́dọ̀ wọ ilé ọmọnìkejì rẹ. Ojú rẹ kò gbọ́dọ̀ wọ aya ọmọnìkejì rẹ, tàbí ẹrúkùnrin rẹ̀ tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀ tàbí akọ màlúù rẹ̀ tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ tàbí ohunkóhun tí ó jẹ́ ti ọmọnìkejì rẹ.”
17  “Não deves desejar  a casa do teu próximo. Não deves desejar a esposa do teu próximo, nem seu escravo, nem sua escrava, nem seu touro, nem seu jumento, nem qualquer coisa que pertença ao teu próximo.”
18  Wàyí o, gbogbo àwọn ènìyàn náà rí ààrá àti ìkọyẹ̀rì mànàmáná àti ìró ìwo àti òkè ńlá tí ń rú èéfín. Nígbà tí àwọn ènìyàn náà rí i, nígbà náà ni wọ́n gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, tí wọ́n sì dúró ní òkèèrè. 
18  Ora, todo o povo presenciava os trovões e os lampejos, e o som da buzina e o monte fumegando. Quando o povo chegou a ver isso, então estremeceu e ficou de longe. 
19  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún Mósè pé: “Ìwọ ni kí ó máa bá wa sọ̀rọ̀, kí a sì máa fetí sílẹ̀; ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí Ọlọ́run bá wa sọ̀rọ̀ kí àwa má bàa kú.”
19  E começaram a dizer a Moisés: “Fala tu conosco, e escutemos; mas não fale Deus conosco, para que não morramos.”
20  Nítorí náà, Mósè wí fún àwọn ènìyàn náà pé: “Ẹ má fòyà, nítorí pé tìtorí dídán yín wò ni Ọlọ́run tòótọ́ fi wá, àti kí ìbẹ̀rù rẹ̀ bàa lè máa wà nìṣó níwájú yín kí ẹ má bàa ṣẹ̀.” 
20  Portanto, Moisés disse ao povo: “Não tenhais medo, porque o [verdadeiro] Deus veio para pôr-vos à prova e para que o temor dele continue diante das vossas faces, para que não pequeis.
21  Àwọn ènìyàn náà sì ń bá a lọ ní dídúró ní òkèèrè, ṣùgbọ́n Mósè sún mọ́ ìwọ́jọpọ̀ àwọsánmà ṣíṣú náà níbi tí Ọlọ́run tòótọ́ wà.
21  E o povo ficou de longe; Moisés, porém, aproximou-se da densa nuvem escura, onde estava o [verdadeiro] Deus.
22  Jèhófà sì ń bá a lọ láti wí fún Mósè pé:“Èyí ni ohun tí ìwọ yóò wí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ‘Ẹ̀yin fúnra yín rí i pé láti ọ̀run wá ni mo ti bá yín sọ̀rọ̀. 
22  E Jeová prosseguiu, dizendo a Moisés: “Isto é o que deves dizer aos filhos de Israel: ‘Vós mesmos tendes visto que foi desde os céus que falei convosco.
23  Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe àwọn ọlọ́run fàdákà pẹ̀lú mi, ẹ kò sì gbọ́dọ̀ ṣe àwọn ọlọ́run wúrà fún ara yín.
23  Não deveis fazer junto de mim deuses de prata, e não deveis fazer para vós deuses de ouro.
24  Pẹpẹ ilẹ̀ ni kí o sì ṣe fún mi, orí rẹ̀ sì ni kí o ti máa rú àwọn ọrẹ ẹbọ sísun rẹ àti àwọn ẹbọ ìdàpọ̀ rẹ, agbo ẹran rẹ àti ọ̀wọ́ ẹran rẹ. Ibi gbogbo tí èmi yóò ti mú kí a rántí orúkọ mi ni èmi yóò ti wá bá ọ, èmi yóò sì bù kún ọ dájúdájú.
24  Deves fazer para mim um altar de terra, e sobre ele tens de sacrificar as tuas ofertas queimadas e os teus sacrifícios de participação em comum, teu rebanho e tua manada. Em todo lugar onde farei que meu nome seja lembrado virei a ti e certamente te abençoarei.
25  Bí ìwọ bá sì fi àwọn òkúta ṣe pẹpẹ fún mi, ìwọ kò gbọ́dọ̀ mọ wọ́n gẹ́gẹ́ bí àwọn òkúta gbígbẹ́. Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé o lo ẹyá rẹ lára rẹ̀ ní ti gidi, nígbà náà, ìwọ yóò sọ ọ́ di aláìmọ́.
25  E se fizeres para mim um altar de pedras, não as deves construir como pedras lavradas. Caso brandas sobre ele a tua talhadeira, profaná-lo-ás.
26  Ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ fi àtẹ̀gùn gun pẹpẹ mi, kí abẹ́ rẹ má bàa hàn lórí rẹ̀.’

26  E não deves subir por degraus ao meu altar, para que as tuas partes pudendas não fiquem expostas nele.’



Nenhum comentário:

Postar um comentário